ÀṢÀ ÌKÍNI TÀBÍ Ẹ̀KỌ́ ILÉ

Category : Uncategorized

 

 

Eléyìí jẹ́ àṣà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Yorùbá fi máa nkọ́ àwọn ọmọ wọn láti kékeré, bí àwọn ọmọ bá ti lè mọ̀ àṣà yìí, kò sí ẹni tí ó lè gbà a ́ lọ́wọ́ wọn mọ́, àwọn ọmọ ilẹ̀ Yorùbá máa nṣe ògo púpọ̀ nínú ẹ̀kọ́ ilé tí wọ́n tètè máa ńfi kọ́ àwọn ọmọ wọn, ṣé Yorùbá bọ̀: wọ́n ní àti kékeré ni a ti npẹ̀ka ìrókò, nítorí tí ó bá ti dàgbà tán kí ó má bàá gbẹ̀bọ lọ́wọ́ ẹni.

Bí ọmọdékùnrin bá ti jí ní òwúrọ̀, ó di dandan kí ó dọ̀bálẹ̀ gbọọrọ láti kí àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí ọmọdébìnrin náà gbọ́dọ̀ kúnlẹ̀ pẹ̀lú orúnkún rẹ̀ méjèèjì ní ilẹ̀, àwọn òbí ẹni nìkan kọ́ ni a máa nkí ní ilẹ̀ Yorùbá; gbogbo àwọn àgbàlagbà àti àwọn tí ó junilọ ni a gbọ́dọ̀ kí bákan náà pẹ̀lú, irú ọmọ tí ó bá ní irú ìwà yìí ni a npè ní ọmọ tí ó ní Ẹ̀kọ́ ilé.

Bí ọmo bá ti nkúnlẹ̀ kí àwọn òbí rẹ̀ bí ó bá jẹ́ obìnrin tàbí dọ̀bálẹ̀ tí ó bá jẹ́ okùnrin tí ó bá ti jí ní òwúrọ̀ ni àwọn òbí irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ yóò dáa lóhùn pé “a ò jíire bí?. Ìdí nìyí tí a fi máa npè àwọn ọmọ Yorùbá ní àwọn ọmọ “káárọ̀ oò jíire”. Òwúrọ̀ nìkan kọ́ ni a máa nkí ara wa ní ilẹ̀ Yorùbá, tí ó bá tin di bíi déédéé agogo mẹ́wàá àbọ̀ sí mọ́kànlá àbọ̀, máa nkí ara wa kú ìyálẹ̀ta. Nígbà tí wọ́n tún máa nkí pé ẹ káàsán ní déédéé agogo mẹ́ta àbọ̀ ọ̀sán.

Ẹ kú ìrọ̀lẹ́ ni a máa nkí ara wa ní déédéé agogo mẹ́rin sí mẹ́fà àbọ̀. Ẹ káalẹ́ ni a máa nkí ara wa ní déédéé agogo méje sí mẹ́wàá àbọ̀ alẹ́ nígbà tí a tún máa nkí pé ó dàárọ̀ o nígbà tí a bá ti fẹ́ lọ sùn lálẹ́.

Yorùbá tún ní oríṣiríṣi ìkíni fún iṣẹ́ òòjọ́ àti àkókò. Fún àpẹẹrẹ:

Aláboyún – Ẹ kú ìkúnra o. Àfọ̀n á gbó kí ó tó wọ̀ o.

Ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ – Ẹ kú ọwọ́ lómi o

Ẹṅi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́lé tuntun – Ẹ̀mí á lò ó. Olúwa a ṣe é ní àlòpẹ́ o.

Ẹni tí ó nṣàìsàn – Orí á kó ọ yọ o.

Ẹni tí bàbá tàbí ìyá rẹ̀ bá kú – Ẹ kú àṣẹ̀yìndè

Ẹni tí ó wà nínú ẹjọ́ – Ọlọ́run á kó ọ yọ o

Ní àkókò ìyàn – A kú àhejẹ o

Ní àkókò ọ̀pọ̀ oúnjẹ – A kú pọ̀pọ̀ṣìnṣìn

Ní àkókò òtútù – A kú ọ̀rinrin yìí o

Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn – A kú ọ̀gbẹlẹ̀ o

Kò sí àkókò tí ó wà tí àwọn ọmọ káárọ̀ oòjíire kò ní ìkíni fún, wọ́n tún ní àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa ngbà kí ọba àti àwọn ìjòyè ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tí ó yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn yòókù. Fún àpẹẹrẹ, a máa ńkí ọba ilú báyìí pé:

Káábíyèsí oo

Kádé pẹ́ lórí

Kí bàtà pẹ́ lẹ́sẹ̀

Ìrùkẹ̀rẹ̀ á di okinni o

Òpó á tirì mọ́lẹ̀ o àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ


Leave a Reply

Archives